EKO BIBELI OJO
ISEGUN
ASE-ALE IGBEYAWO ODO-AGUNTAN
(Ifihan 19:5-9)
IFAARA
“E je
ki a yo, ki inu wa ki o si dun gidigidi, ki a si fi ogo fun-Un; nitori pe igbeyawo Odo-Aguntan de, aya Re si ti mura tan” (Ifihan 19:7).
N je a ti ni anfaani lati kopa nibi igbeyawo olowo
tabi borokinni eniyan ri? N je a ti bawon lo sibi igbeyawo ni aafin oba ti o ni
sekedu owo bi? Igbeyawo yato si igbeyawo niti ara. Igbeyawo laarin awon iranse
Olorun wa; ti awon osise nikan wa; ti gbo-gbo-gboo si wa pelu. Inawo won yato
si ara won, sugbon ibukun kan
naa ni o ni.
Ipadabo Oluwa leekeji je isele ayo fun awon
ti a ti gbala, ti a so di mimo, ti won si n murasile fun igbasoke awon ayanfe
loore-koore. Sugbon, yoo je ohun ibanuje fun awon alainigbala, asako ati awon
ti ona won ko to. Ki i se gbogbo eniyan ni yoo ni anfaani lati kopa nibi Ase-Ale
Igbeyawo Odo-Aguntan ti a n so yii. Awon ti won kogo ja ninu ere ije ti
aye yii ni won yoo ni anfaani lati le wo gbongan naa. Iru awon bee ti bo lowo
wahala, osi, are, idaamu ati laasigbo inu aye. Awon wonyii ni won ti soda omi ki
afara o too ja. Awon wonyii ni irin-ajo won ninu aye ko ja si asan. Won
ko se wahala lasan. Won kogo ja, won si de ibi isinmi ayeraye. Won ko si ninu
egbe awon ti won yoo bawon kabamo ayeraye. Won de enu ibode orun, won ni iwe
eri igbala, iwa mimo, atunse, alaafia pelu gbogbo eniyan, eso ti emi ati ise
isin tabi iriju. Leke gbogbo re, won ri aanu Olorun gba.
1. IMURASILE AWON ONIGBAGBO (Ifihan 19:7)
Gbolohun aya Re n toka si ijo, ara
awon onigbagbo, ki i se ile ti a fi oju ri. Ninu Majemu laelae, a fi awon
eniyan Olorun pe awon ti won ni eto si majemu igbeyawo pelu Olorun Olodumare. “Nitori Eleda re ni oko re: Oluwa awon omo
ogun ni oruko re; ati Olurapada re Eni-Mimo Isireli; Olorun agbaye ni a o maa pe
E” (Isaya 54:5). Wayii, Kristi ni baale tabi oko iyawo nigba
ti ijo
je iyawo tabi aya. Bi a ti n soro nipa imurasile awon onigbagbo, a n
soro nipa imurasile aya Kristi.
Lati le kopa ninu Ase-Ale Igbeyawo Odo-Aguntan,
imurasile ti o peye se pataki, a si n beere re. Oluwa so eyi taara ninu Owe
wundia mewaa (Matiu 25:1-13).
Awon wundia mewaa yii ni ibasepo pelu oko-iyawo, sugbon awon alaigbon laarin
won ko murasile. Ki i se gbogbo awon ti won n gbe bibeli ni won gbon. Ogbon
Olorun yii ni o maa n gba ironipiwada, atunse,
isodimimo ati ododo lowo eniyan ki a to lee di aya Kristi (I Johanu 3:3; Matiu 24:36-39).
2. IWA
FUNFUN TI IYAWO (Ifihan 19:8)
“Oun ni a si fi fun pe ki o wo aso ogbo wiwe
ti o funfun gboo:nitori pe aso ogbo wiwe ni ni ise ododo awon eniyan mimo”.
Awon eniyan ti yoo ye fun ijoba Olorun ni awon eni
mimo nikan soso. Ki i se awon elese tabi apadaseyin. Poolu wi pe “Si
gbogbo eni ti o wa ni Roomu, olufe Olorun, ti a pe lati je mimo…” (Roomu 1:7). Oluwa n reti awon ti won
mo O, ti won si n tele E. Awon kristieni alafenuje ko ni Olorun n wa. O wi pe ”Ko
awon eniyan mimo mi jo po si odo Mi:awon ti o fi ebo ba mi da majemu (Orin Dafidi 50:5).
Ninu
Majemu Laelae, awon oniruuru irubo meji ni o wa:
(i)
Fifi eranko rubo
(ii)
Fifi ara eni rubo
Ninu
Majemu Tuntun, irubo ti Odo-Aguntan n be ati irubo ara eni. Jesu fi
ara Re rubo fun ese wa, bee naa ni a ni lati fi ara wa rubo (ki a fi ara wa ji,
ki a yooda eya ara wa fun Olorun) gege bi i Roomu
12:1 se so pe “… ki eyin ki o fi ara yin fun Olorun ni ebo aaye, mimo, itewogba, eyi
ti i se ise isin yin ti o tona”. Ti ise isin wa si Olorun ko ba se
itewogba, asinnu lasan ni a n pe iru ise isin bee. Ko ni itewogba l’odo Olorun.
Ko si gbe onitohun koja lo si orun nitori ko ni oote Olorun rara. Iru eni
bee n sise ti ko ni ere orun. Iru eni bee n wa si ile ijosin lasan. Iru awon
wonyii ni Olorun yoo so fun pe “Kuro niwaju mi, iwo onise ese”. Iru ipo wo ni o wa
niwaju Olorun? Iru ise wo ni o n se fun-Un?
Awon nnkan kan
wa ti o ye awon eniyan mimo – iru awon aso kan,
oro, ise ati ibasepo kan.
Awon eniyan ti yoo kopa nibi Ase-Ale Igbeyawo Odo-Aguntan ni awon
eni ti o ni abuda iwa mimo. Oko iyawo n fe ki iyawo ti oun fe fe ki o je
mimo. Iwa mimo ati ododo ni a tenumo gege bi ohun ti o se pataki fun
kikopa nibi Ase-Ale igbeyawo Odo-Aguntan. Igbe-aye iwa mimo gbodo je
akomona wa nibi gbogbo. Poolu wi pe “Ijo ti o ni ogo, ni aini abawon tabi aleebu
kan, tabi iru
nnkan bawon-ni; sugbon ki o lee je mimo ati alaini abuku” (Efesu 5:25-27).
3. AWON ALABAPIN IBUKUN NAA (Ifihan 19:9)
“O si wi
fun mi pe, kowe re, ibukun ni fun awon
ti a pe si ase-ale igbeyawo Odo Aguntan. O si wi fun mi pe, wonyii ni oro otito Olorun”.
Ki i se gbogbo eniyan ni yoo
kopa nibi ase ti a n so yii. Gbogbo awon ti won n wa si inu ijo ko ni yoo kopa.
Gbogbo oniwaasu ko ni o maa wa nibe. Ki i se gbogbo osise ni o maa wa ninu
gbongan naa. Akorin ti yoo wa nibe ko ni po rara. Awon olutoju ile isin ti yoo
wa nibe yoo je iwonba kereje. Awon oludasile ijo ti yoo wa nibi Ase-Ale
Igbeyawo Odo-Aguntan ko ni po rara. Awon ti won gbonran si ase Olorun
ni yoo kopa nibe. Olorun n se akosile awon ti o n se ise pelu okan mimo sile.
Oju kan wa ti
o n wo o nibikibi ti o ba lo. Eti kan
wa ti o n teti si ohun gbogbo ti o n so ninu gbogbo ijiroro ti o lowo si. N je
a ti we o ninu eje Odo Aguntan naa?
Ilekun igbala ko ni pe ti mo. Aye
yii n yi bi owo aago lo si opin. Ni kete ti ipe ikeyin ba ti dun, opin
de ba gbogbo nnkan nile aye. Gbogbo asotele inu Iwe Mimo se tan niyen. Gbogbo
giragira eda dopin. Awa ti a ba gbagbo dunju ni yoo ba Jesu lo nigba Igbasoke
Awon Eni Mimo. Ti o ba kopa ninu igbasoke, o ti kogo ja ninu awon isele
ti o ku. O bo ninu wahala aye, o bo ninu eto oselu ile aye, o bo lowo awon
amunisin ile aye, o bo lowo awon eni ibi ti n be nile aye. Opin de ba gbogbo
laasigbo ti a n dojuko nile aye.
Ki Olorun o di koowa wa mu titi de opin (amin).
IPARI
Bi o ba maa kopa nibi Ase-Ale Igbeyawo Odo-Aguntan,
o ni lati jawo ninu gbogbo iregbe, ki o pinnu lati tele Olorun dunju. Ohunkohun
ti yoo gba ni o ni lati fi fun-Un. Igbadun ibe ko ni afiwe. Ewa ibe ko ni
akawe. Ti enikeni ba kuna ninu igbasoke, ilekun ijiya si sile fun onitothun
niyen. O di eni egbe ayeraye. O si kanrinkese pelu.
Gbe igbesi aye iwa mimo. Mase koworin pelu
awon ti won ko ni orun-un lo. Ki Olorun o ka iwo olugbo ati oluse oro yii ye nibi Ase-Ale
Igbeyawo Odo-Aguntan ni oruko Jesu (amin).
“Bi o ba mo nnkan wonyii,
alabukun-fun ni o bi o ba n se won” –Johanu
13:17.
ALAGBA ADU OLUGBENGA NI O SE
AKOSILE EKO BIBELI YII