IPINLE IGBESI AYE EMI TI O DURO SANSAN






IPINLE IGBESI AYE EMI TI O DURO SANSAN
(Luuku 6:46-49)

“Eesitise ti eyin n pe mi ni Oluwa, Oluwa, ti eyin ko si se ohun ti mo wi? Enikeni ti o tomi wa, ti o si n gbe oro Mi, ti o si n se e, Emi o fi eni ti o jo han yin. O jo okunrin kan ti o ko ile, ti o si wale jin, ti o si fi ipinle sole lori apata: nigba ti kikun omi de, igbi-omi bilu ile na, ko si le mi i: nitori ti a fi ipinle re sole lori apata. Sugbon eni ti o gbo, ti ko si se, o dabi okunrin ti o ko ile si ori ile laini ipinle; nigba ti igbi-omi bilu u, logan o si wo; iwo ile naa si po”.
- Luuku 6:46-49. 

IFAARA

 Enikookan wa ni o ni ibere nile aye. Ko si eni ti o dede hu jade gege bi igi. O ni ibi ti a ti san jade wa. Enikookan ni o si ni ipinle. Bi ipinle enikookan se ri ni o yato si ara won. Eredi niyi ti o ye fun koowa wa lati beere pe kin ni ipinle?kin ni a n pe ni igbesi aye emi? Kin ni a n pe ni ki nnkan o duro sansan?
   Ewe, eni ti o ba fe se ipinle ile ti o dara, ti ko ni si beru nigba ti ojo ba de, gbodo mo bi a se n ko ile pelu sanmonti ti a fi irin se si isale ile naa. Igbesi aye emi ni o mu ironupiwada tooto jade wa. Eyi ki i se ironupiwada ori ahon, tabi eyi ti o fi han pe mo n lo si soosi. Ironipiwada tooto ni yiyipada kuro ninu iwa wa atijo gege bi i Johanu 3:3; Roomu 12:1 se so. Ki nnkan o duro sansan ni ki nnkan o wa laiyese, ti ko si nnkan ti o le mi i, ti o duro gboin-gboin. Iyen ni pe, ki eniyan o duro lori ihinrere ti o gba laiyese rara (Danieli 3:16-18).
  Iru igbesi aye wo ni iwo n gbe? Se eyi ti o duro sansan ni tabi igbesi aye gbefe? Ye igbesi aye tire wo loni. N je a ti ko iwo olugbo ati onkawe yii ni ila aya ti emi bi?

1. BAWO NI A SE LE MO KRISTIENI TI O N GBE IGBESI AYE TI O DURO SANSAN?
                              (Roomu 8:35-39; I Timotiu 4:12; Matiu 7:16).

1.      Nipa iwa won ati ise won ni a o fi mo won (Matiu 7:16)
2.      Oro ti o n jade lati enu yoo fi iru eni ti o je han(I Timotiu 4:12)
3.      Iwa ti yoo hu ni ile ati ita pelu (Matiu 7:16)
4.      Sise ife Olorun (I Timotiu 6:6; I Timotiu 4:8)
5.      Igbesi aye iwa mimo ti ko ni abawon (Heberu 12:14; Isaya 35:8-10)
6.      Won yoo ni ife omonikeji won (Jakobu 1:16-17)
7.      Kika oro Olorun ati mimu lo sinu ise (Orin Dafidi 119:112; Jakobu 1:22-23)
8.      Isoro ki i dori won ko odo (Danieli 6:22)
9.      Rinrin deede niwaju Olorun  (II Tesalonika 3:6)
10.  Ni akoko ijosin, a ki i wa won ti.
11.  Won fi owo ti o dara mu adura gbigba (Matiu 21:21-22)
12.  Igbagbo won mu ise dani, won si n se fun Oluwa (Jakobu 2:14-17)

 2.  BI A SE N MO KRISTIENI TI KO NI IPINLE TI O DURO SANSAN
                           (Galatia 5:19-21; Matiu 7:16)

1.      Nipa iwa ati ise won ni a o fi mo won.
2.      Awon nnkan ti emi maa n nira fun won lati se loore-koore.
3.      Akoko ijosin ko ni itumo si won rara.
4.      Iwaju Oluwa yoo dabi eni ti n lo oja fun iru won.
5.      Oro ehin, fifi oro kele bani je yoo jaraba won..
6.      Igbesi aye agbere, iro, ofofo sise ni o  pekun si odo won (I Korinti 3:16-19)
7.      Fifi ipa wa owo ojiji
8.      Sise efe asan tabi isefe asan. Fifi oro Olorun se efe pelu. Won ko ni bikita fun oro Olorun.
  E je ki a gbe ara wa le ori osuwon. Se ipinle igbesi aye wa duro sansan bi?  (Roomu 12:1-2; I Korinti 4:1-2).

IKADII

 Jesu so pe: “Enikeni ti o ba fe tomi leyin, je ki o se ara re, ki o gbe agbelebu re, ki o si maa tomi leyin”.

GHB 240 ka bayi:

1.   Jesu mo gb’agbelebu mi,           2.     Eda le maa wahala mi.
      Ki n le maa to O leyin,                      Yoo mu mi sunmo O ni,
     Otosi, at’eni egan,                              Idanwo aye le ba mi,
       ‘Wo l’ohun gbogbo fun mi,                 Orun yoo mu ‘sinmi wa,
     Bi ini mi gbogbo segbe,                      Ibanuje ko le se nnkan,
     Ti ero mi gbogbo pin,                         B’ife Re ba wa fun mi,
     Sibe oloro ni mo je!                            Ayo ko si le dun mo mi,
     T’emi ni Kristi’ at’orun.                    B’iwo o si ninu Re.


“Bi o ba mo nnkan wonyii, alabukun-fun ni o bi o ba n se won”
                             –Johanu 13:17
PREPARED AND DELIVERED BY DEACON ARIBISALA PAUL